맥체인 성경 여정

성경읽기표 — 맥체인 1년 통독

성경읽기표를 따라 하루 4본문을 읽으며 1년에 구약 1회, 신약과 시편을 2회 통독합니다.

365 1년 고정 통독표
4 하루 4본문
365 선택한 일차
‹ 365일차 / 총 365일 ›
역본

통독 확인

이 일차의 맥체인 본문을 완료했나요?

확인 버튼을 누르면 마이페이지 맥체인 진도표에 완료로 기록됩니다.

가정 예배 · 구약

역대하 36

본문 열기 →
36장

The Reigns of Jehoahaz and Jehoiakim

1Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jehoahasi ọmọ Josiah wọn sì fi jẹ ọba ní Jerusalẹmu ni ipò baba rẹ̀.

2Jehoahasi sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta.

3Ọba Ejibiti yọ kúrò lórí ìtẹ́ ní Jerusalẹmu, ó sì bù fún un lórí Juda, ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà àti tálẹ́ǹtì wúrà kan.

4Ọba Ejibiti sì mú Eliakimu, arákùnrin Joahasi, jẹ ọba lórí Juda àti Jerusalẹmu, ó sì yí orúkọ Eliakimu padà sí Jehoiakimu, ṣùgbọ́n Neko mú Joahasi arákùnrin Eliakimu lọ sí Ejibiti.

5Jehoiakimu sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìlá. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

6Nebukadnessari ọba Babeli sì mú un, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti mú un lọ sí Babeli.

7Nebukadnessari kó nínú ohun èlò ilé Olúwa lọ si Babeli pẹ̀lú, ó sì fi wọn sí ààfin rẹ̀ ní Babeli.

8Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àwọn ohun ìríra tí ó ṣe àti gbogbo ohun tí a rí nípa rẹ̀, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Israẹli àti Juda. Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

The Reigns of Jehoiachin and Zedekiah

9Jehoiakini sì jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ́ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́wàá ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa.

10Ní àkókò òjò, ọba Nebukadnessari ránṣẹ́ sí i ó sì mú un wá sí Babeli, pẹ̀lú ohun èlò dáradára láti ilé Olúwa, ó sì mú arákùnrin Jehoiakini, Sedekiah, jẹ ọba lórí Juda àti Jerusalẹmu.

11Sedekiah jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlá.

12Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, kò sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jeremiah wòlíì ẹni tí ó sọ̀rọ̀ Olúwa.

13Ó sì tún ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Nebukadnessari pẹ̀lú, ẹni tí ó mú kí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra. Ó sì di ọlọ́run líle, ó sì mú ọkàn rẹ̀ le láti má lè yípadà sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.

14Síwájú sí i gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn sì di ẹni tí ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi, pẹ̀lú gbogbo ìríra àwọn orílẹ̀-èdè wọ́n sì sọ ilé Olúwa di èérí, tí ó ti yà sí mímọ́ ní Jerusalẹmu.

15Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn ránṣẹ́ sí wọn láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, nítorí tí ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ àti sí ibùgbé rẹ̀.

16Ṣùgbọ́n wọ́n ń kùn sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣẹ̀sín títí tí ìbínú Olúwa fi ru sórí wọn, sí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì ṣí àtúnṣe.

The Fall of Jerusalem and the Babylonian Exile

17Ó sì mú wá sórí wọn ọba àwọn ará Babeli tí wọ́n bá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn jà pẹ̀lú idà ní ilẹ̀ ibi mímọ́, kò sì ní ìyọ́nú sí àgbà ọkùnrin tàbí ọ̀dọ́mọdébìnrin, wúńdíá, tàbí arúgbó. Ọlọ́run sì fi gbogbo wọn lé Nebukadnessari lọ́wọ́.

18Ó sì mú gbogbo ohun èlò láti ilé Ọlọ́run lọ sí Babeli, ńlá àti kékeré àti ìṣúra ilé Olúwa àti ìṣúra ọba àti ìjòyè rẹ̀.

19Wọ́n sì fi iná sun ilé Ọlọ́run, wọ́n sì wó gbogbo ògiri ilé Jerusalẹmu, wọ́n sì jó gbogbo ààfin wọn, wọ́n sì ba gbogbo ohun èlò ibẹ̀ jẹ́.

20Ó sì kó èyí tí ó kù lọ sí Babeli àwọn tí ó rí ibi sá kúrò lẹ́nu idà wọ́n sì di ìránṣẹ́ fún un àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí tí ìjọba Persia fi gba agbára.

21Ilẹ̀ náà sì gbádùn ìsinmi rẹ̀, ní gbogbo ìgbà ìdahoro, òun sì ń sinmi títí àádọ́rin ọdún fi pé ní ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ láti ẹnu Jeremiah.

The Decree of Cyrus for the Return

22Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi ọba Persia, kí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a tẹnu Jeremiah sọ bá à le ṣẹ pé, Olúwa run ẹ̀mí Kirusi ọba Persia láti ṣe ìkéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì kọ ọ́ sínú ìwé pẹ̀lú.

23“Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia sọ wí pé:

가정 예배 · 신약

요한계시록 22

본문 열기 →
22장

The River of the Water of Life and the Tree of Life

1Ó sì fi odò omi ìyè kan hàn mi, tí ó mọ́ bí kirisitali, tí ń tí ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn jáde wá,

2ní àárín ìgboro rẹ̀, àti níhà èkínní kejì odò náà, ni igi ìyè gbé wà, tí o máa ń so onírúurú èso méjìlá, a sì máa so èso rẹ̀ ni oṣooṣù ewé igi náà sí wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè láradà.

3Ègún kì yóò sì ṣí mọ: ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-àgùntàn ni yóò sì máa wà níbẹ̀; àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò sì máa sìn ín.

4Wọ́n ó si máa rí ojú rẹ̀; orúkọ rẹ̀ yóò si máa wà ni iwájú orí wọn.

5Òru kì yóò sí mọ́; wọn kò sì ní wa ìmọ́lẹ̀ fìtílà, tàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn; nítorí pé Olúwa Ọlọ́run ni yóò tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn: wọn ó sì máa jẹ ọba láé àti láéláé.

The Promise of Coming Soon and the Warning

6Ó sì wí fún mi pé, “Òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Olúwa Ọlọ́run ẹ̀mí àwọn wòlíì ni ó sì ran angẹli rẹ̀ láti fi ohun tí ó ní láti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí hàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.”

7“Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán! Ìbùkún ni fún ẹni tí ń pa ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́!”

8Èmi, Johanu, ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó sì ri nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí mo sì gbọ́ tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti foríbalẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ angẹli náà, tí o fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi.

9Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Wó ò, má ṣe bẹ́ẹ̀, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ wòlíì, àti ti àwọn tí ń pa ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí mọ́. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run!”

10Ó sì wí fún mi pé, “Má ṣe fi èdìdì di ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí inú ìwé yìí, nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀.

11Ẹni tí ń ṣe aláìṣòótọ́, kí ó máa ṣe aláìṣòótọ́ nì só; àti ẹni tí ń ṣe ẹlẹ́gbin, kí ó máa ṣe ẹ̀gbin nì só; àti ẹni tí ń ṣe olódodo, kí ó máa ṣe òdodo nì só; àti ẹni tí ń ṣe mímọ́, kí ó máa ṣe mímọ́ nì só.”

12“Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán; èrè mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi, láti sán fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ yóò tí rí.

13Èmi ni Alfa àti Omega, ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin.

14“Ìbùkún ni fún àwọn ti ń fọ aṣọ wọn, kí wọ́n lè ni ẹ̀tọ́ láti wá sí ibi igi ìyè náà, àti kí wọ́n lè gbà àwọn ẹnu ibodè wọ inú ìlú náà.

15Nítorí ni òde ni àwọn ajá gbé wà, àti àwọn oṣó, àti àwọn àgbèrè, àti àwọn apànìyàn, àti àwọn abọ̀rìṣà, àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn èké tí ó sì ń hùwà èké.

The Final Testimony and the Plea for the Lord

16“Èmi, Jesu, ni ó rán angẹli mi láti jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí fún yin ní tí àwọn ìjọ. Èmi ni gbòǹgbò àti irú-ọmọ Dafidi, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tí ń tàn.”

17Ẹ̀mí àti ìyàwó wí pé, “Máa bọ!” Àti ẹni tí ó ń gbọ́ kí ó wí pé, “Máa bọ̀!” Àti ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ kí ó wá, àti ẹni tí o bá sì fẹ́, kí ó gba omi ìyè náà lọ́fẹ̀ẹ́.

18Èmi kìlọ̀ fún olúkúlùkù ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí pé, bí ẹnikẹ́ni ba fi kún wọn, Ọlọ́run yóò fi kún àwọn ìyọnu tí a kọ sínú ìwé yìí fún un.

19Bí ẹnikẹ́ni bá sì mú kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìwé ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ọlọ́run yóò sì mú ipa tirẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, àti kúrò nínú ìlú mímọ́ náà, àti kúrò nínú àwọn ohun tí a kọ sínú ìwé yìí.

20Ẹni tí ó jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí wí pé, “Nítòótọ́ èmi ń bọ̀ kánkán.”

21Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. Àmín.

개인 경건 · 구약/시편

말라기 4

본문 열기 →
4장

The Day of the Lord and the Sun of Righteousness

1“Dájúdájú, ọjọ́ náà ń bọ̀; tí yóò máa jó bi iná ìléru. Gbogbo àwọn agbéraga, àti gbogbo àwọn olùṣe búburú yóò dàbí àgékù koríko: ọjọ́ náà tí ń bọ̀ yóò si jó wọn run,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Ti ki yóò fi kù gbòǹgbò kan tàbí ẹ̀ka kan fún wọn.

2Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, oòrùn òdodo yóò yọ, pẹ̀lú ìmúláradá ni ìyẹ́ apá rẹ̀. Ẹ̀yin yóò sì jáde lọ, ẹ̀yin yóò sì máa fò fún ayọ̀ bi àwọn ẹgbọrọ màlúù tí a tú sílẹ̀ lórí ìso.

3Ẹ̀yin yóò sì tẹ àwọn ènìyàn búburú mọ́lẹ̀: nítorí wọn yóò di eérú lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ náà tí èmi yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

I Will Send Elijah

4“Ẹ rántí òfin Mose ìránṣẹ́ mi, àwọn ìlànà àti òfin èyí tí mo fún un ní Horebu fún gbogbo Israẹli.”

5“Wò ó, èmi yóò rán wòlíì Elijah sí i yín, ki ọjọ́ ńlá, ọjọ́ ẹ̀rù Olúwa to dé.

6Òun yóò sì pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ọkàn àwọn ọmọ sì ti àwọn baba wọn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò wá, èmi yóò sì fi ilẹ̀ náà gégùn.”

개인 경건 · 신약

요한복음 21

본문 열기 →
21장

Jesus Appears at the Sea of Tiberias

1Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu tún fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ létí Òkun Tiberia; báyìí ni ó sì farahàn.

2Simoni Peteru, àti Tomasi tí a ń pè ní Didimu, àti Natanaeli ará Kana ti Galili, àti àwọn ọmọ Sebede, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjì mìíràn jùmọ̀ wà pọ̀.

3Simoni Peteru wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ pẹja!” Wọ́n wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú ń bá ọ lọ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ inú ọkọ̀ ojú omi; ní òru náà wọn kò sì mú ohunkóhun.

4Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ́, Jesu dúró létí Òkun, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jesu ni.

5Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọdé, ẹ ní ẹja díẹ̀ bí?”

6Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ sọ àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ̀yin yóò sì rí.” Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọn kò sì lè fà á jáde nítorí ọ̀pọ̀ ẹja.

7Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà tí Jesu fẹ́ràn wí fún Peteru pé, “Olúwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Olúwa ni, bẹ́ẹ̀ ni ó di àmùrè ẹ̀wù rẹ̀ mọ́ra, nítorí tí ó wà ní ìhòhò, ó sì gbé ara rẹ̀ sọ sínú Òkun.

8Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù mú ọkọ̀ ojú omi kékeré kan wá nítorí tí wọn kò jìnà sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ìwọ̀n igba ìgbọ̀nwọ́; wọ́n ń wọ́ àwọ̀n náà tí ó kún fún ẹja.

9Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹ̀yín iná níbẹ̀ àti ẹja lórí rẹ̀ àti àkàrà.

10Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú nínú ẹja tí ẹ pa nísinsin yìí wá.”

11Nítorí náà, Simoni Peteru gòkè, ó sì fa àwọ̀n náà wálẹ̀, ó kún fún ẹja ńlá, ó jẹ́ mẹ́tàléláàádọ́jọ (153) bí wọ́n sì ti pọ̀ tó náà, àwọ̀n náà kò ya.

12Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun òwúrọ̀.” Kò sì sí ẹnìkan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó jẹ́ bí i pé, “Ta ni ìwọ ṣe?” Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni.

13Jesu wá, ó sì mú àkàrà, ó sì fi fún wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹja.

14Èyí ni ìgbà kẹta nísinsin yìí tí Jesu farahan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú.

Jesus Restores Peter

15Ǹjẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹun òwúrọ̀ tan, Jesu wí fún Simoni Peteru pé, “Simoni, ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí?”

16Ó tún wí fún un nígbà kejì pé, “Simoni ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ mi bí?”

17Ó wí fún un nígbà kẹta pé, “Simoni, ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ràn mi nítòótọ́ bí?”

18Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, nígbà tí ìwọ wà ní ọ̀dọ́mọdé, ìwọ a máa di ara rẹ ní àmùrè, ìwọ a sì máa rìn lọ sí ibi tí ìwọ bá fẹ́, ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá di arúgbó, ìwọ yóò na ọwọ́ rẹ jáde, ẹlòmíràn yóò sì dì ọ́ ní àmùrè, yóò mú ọ lọ sí ibi tí ìwọ kò fẹ́.”

19Jesu wí èyí, ó fi ń ṣe àpẹẹrẹ irú ikú tí yóò fi yin Ọlọ́run lógo. Lẹ́yìn ìgbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

20Peteru sì yípadà, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn náà, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ń bọ̀ lẹ́yìn; ẹni tí ó gbara le súnmọ́ àyà rẹ̀ nígbà oúnjẹ alẹ́ tí ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ta ni ẹni tí yóò fi ọ́ hàn?”

21Nígbà tí Peteru rí i, ó wí fún Jesu pé, “Olúwa, Eléyìí ha ń kọ́?”

22Jesu wí fún un pé, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kín ni èyí jẹ́ sí ọ? Ìwọ máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

23Ọ̀rọ̀ yìí sì tàn ká láàrín àwọn arákùnrin pé, ọmọ-ẹ̀yìn náà kì yóò kú, ṣùgbọ́n Jesu kò wí fún un pé, òun kì yóò kú; ṣùgbọ́n, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kín ni èyí jẹ́ sí ọ?”

24Èyí ni ọmọ-ẹ̀yìn náà, tí ó jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí, àwa sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀.

25Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun mìíràn pẹ̀lú ni Jesu ṣe, èyí tí bí a bá kọ̀wé wọn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo rò pé gbogbo ayé pàápàá kò lè gba ìwé náà tí a bá kọ ọ́.