麦琴圣经旅程

麦琴一年读经计划

每天四处经文,一年读旧约一遍、新约和诗篇两遍。

365 一年固定读经表
4 每天四处经文
269 所选天数
‹ 第269天 / 共365天 ›
译本

读经确认

你完成了这一天的麦琴读经吗?

点击确认后,会在我的页面麦琴进度表中记录为已完成。

家庭崇拜·旧约

사무엘하 22

打开经文 →
第22章

David's Song of Thanksgiving

1Dafidi sì kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sí Olúwa ní ọjọ́ tí Olúwa gbà á kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ Saulu.

2Ó sì wí pé,

3Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò,

4“Èmi ké pe Olúwa, tí ó yẹ láti máa yìn,

5Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri;

6Ọ̀já isà òkú yí mi káàkiri;

7“Nínú ìpọ́njú mi, èmi ké pé Olúwa,

8Ilẹ̀ sì mì, ó sì wárìrì;

9Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá,

10Ó tẹ orí ọ̀run ba pẹ̀lú, ó sì sọ̀kalẹ̀;

11Ó sì gun orí kérúbù, ó sì fò,

12Ó sì fi òkùnkùn ṣe ibùjókòó yí ara rẹ̀, àti àgbájọ omi,

13Nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀

14Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá,

15Ó sì ta ọfà, ó sì tú wọn ká;

16Ìṣàn ibú òkun sì fi ara hàn,

17“Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi;

18Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,

19Wọ́n wá láti borí mi lọ́jọ́ ìpọ́njú mi,

20Ó sì mú mi wá sí ààyè ńlá,

21“Olúwa sán án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;

22Nítorí pé èmi pa ọ̀nà Olúwa mọ́,

23Nítorí pé gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ ni ó wà níwájú mi;

24Èmi sì wà nínú ìwà títọ́ sí í,

25Olúwa sì san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,

26“Fún aláàánú ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ni aláàánú,

27Fún onínú funfun ni ìwọ fi ara rẹ hàn ní funfun;

28Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìyà ni ìwọ ó sì gbàlà;

29Nítorí ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, Olúwa;

30Bẹ́ẹ̀ ni nítorí nípa rẹ̀ ni èmi ti la àárín ogun kọjá;

31“Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀;

32Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe Olúwa?

33Ọlọ́run alágbára ni ó fún mi ní agbára,

34Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín;

35Ó kọ́ ọwọ́ mi ní ogun jíjà;

36Ìwọ sì ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ̀;

37Ìwọ sì sọ ìtẹ̀lẹ̀ di ńlá ní abẹ́ mi;

38“Èmi ti lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì ti run wọ́n,

39Èmi ti pa wọ́n run, èmi sì ti fọ́ wọn,

40Ìwọ sì ti fi agbára dì mí ní àmùrè fún ìjà;

41Ìwọ sì mú àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà fún mi,

42Wọ́n wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti gbà wọ́n;

43Nígbà náà ni èmi sì gún wọn wẹ́wẹ́ bí erùpẹ̀ ilẹ̀,

44“Ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìjà àwọn ènìyàn mi,

45Àwọn àjèjì wá láti tẹríba fún mi;

46Àyà yóò pá àwọn àlejò,

47“Olúwa ń bẹ́; olùbùkún sì ni àpáta mi!

48Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbẹ̀san mi,

49Àti ẹni tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

50Nítorí náà èmi ó fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa,

51“Òun ni ilé ìṣọ́ ìgbàlà fún ọba rẹ̀;

家庭崇拜·新约

갈라디아서 2

打开经文 →
第2章

The Gospel to the Gentiles Affirmed by the Apostles

1Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá, ni mo tún gòkè lọ sì Jerusalẹmu pẹ̀lú Barnaba, mo sì mú Titu lọ pẹ̀lú mi.

2Mo gòkè lọ nípa ohun ti a fihàn mi, mo fi ìyìnrere náà tí mo ń wàásù láàrín àwọn aláìkọlà yé àwọn tí ó jẹ́ ẹni ńlá nínú wọn, èyí i nì ní ìkọ̀kọ̀, kí èmi kí ó má ba á sáré, tàbí kí ó máa ba à jẹ́ pé mo ti sáré lásán.

3Ṣùgbọ́n a kò fi agbára mú Titu tí ó wà pẹ̀lú mi, ẹni tí í ṣe ara Giriki láti kọlà.

4Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nítorí àwọn èké arákùnrin tí wọn yọ́ wọ inú àárín wa láti yọ́ òmìnira wa wò, èyí tí àwa ni nínú Kristi Jesu, kí wọn lè mú wa wá sínú ìdè.

5Àwọn ẹni ti a kò fún ni àǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn fún ìṣẹ́jú kan; kí ẹ̀yin kí o lè máa tẹ̀síwájú nínú òtítọ́ ìyìnrere náà.

6Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ó dàbí ẹni pàtàkì—ohunkóhun tí ó wù kì wọn jásí, kò jẹ́ nǹkan kan fún mi; Ọlọ́run kò fi bí ẹnikẹ́ni ṣe rí ṣe ìdájọ́ rẹ̀—àwọn ènìyàn yìí kò fi ohunkóhun kún ọ̀rọ̀ mi.

7Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọn rí i pé a tí fi ìyìnrere tí àwọn aláìkọlà le mi lọ́wọ́, bí a tí fi ìyìnrere tí àwọn onílà lé Peteru lọ́wọ́.

8Nítorí Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Peteru gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn Júù, òun kan náà ni ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn aláìkọlà.

9Jakọbu, Peteru, àti Johanu, àwọn ẹni tí ó dàbí ọ̀wọ́n, fún èmi àti Barnaba ni ọwọ́ ọ̀tún ìdàpọ̀ nígbà tí wọ́n rí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, wọ́n sì gbà pé kí àwa náà tọ àwọn aláìkọlà lọ, nígbà ti àwọn náà lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù.

10Ohun gbogbo tí wọ́n béèrè fún ni wí pé, kí a máa rántí àwọn tálákà, ohun kan náà gan an tí mo ń làkàkà láti ṣe.

Paul Rebukes Peter at Antioch

11Ṣùgbọ́n nígbà tí Peteru wá sí Antioku, mo takò ó lójú ara rẹ̀, nítorí tí ó jẹ̀bi, mo sì bá a wí.

12Nítorí pé kí àwọn kan tí ó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu wá tó dé, ó ti ń ba àwọn aláìkọlà jẹun; ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó fàsẹ́yìn, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà nítorí ó bẹ̀rù àwọn ti ó kọlà.

13Àwọn Júù tí ó kù pawọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti jùmọ̀ ṣe àgàbàgebè, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn sì fi àgàbàgebè wọn si Barnaba lọ́nà.

14Nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn déédé gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìyìnrere, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ, tí ì ṣe Júù ba ń rìn gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn kèfèrí, èéṣe tí ìwọ fi ń fi agbára mu àwọn kèfèrí láti máa rìn bí àwọn Júù?

Justified by Faith

15“Àwa tí i ṣe Júù nípa ìbí, tí kì i sí ì ṣe aláìkọlà ẹlẹ́ṣẹ̀,

16tí a mọ̀ pé a kò dá ẹnikẹ́ni láre nípa iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, àní àwa pẹ̀lú gbà Jesu Kristi gbọ́, kí a bá a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ tí Kristi, kì í sì i ṣe nípa iṣẹ́ òfin, nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin kò sí ènìyàn kan tí a ó dá láre.

17“Ṣùgbọ́n nígbà tí àwa bá ń wá ọ̀nà láti rí ìdáláre nípa Kristi, ó di ẹ̀rí wí pé àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ǹjẹ́ èyí ha jásí wí pé Kristi ń ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí ì!

18Nítorí pé bí mo bá sì tún gbé àwọn ohun tí mo tí wó palẹ̀ ró, mo fi ara mi hàn bí arúfin.

19“Nítorí pé nípa òfin, mo tí di òkú sí òfin, kí èmi lè wà láààyè sí Ọlọ́run.

20A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kristi, èmí kò sì wà láààyè mọ́, ṣùgbọ́n Kristi ń gbé inú mi wíwà tí mo sì wà láààyè nínú ara, mo wà láààyè nínú ìgbàgbọ́ Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí o fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkára rẹ̀ fún mi.

21Èmi kò ya oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sí apá kan, nítorí pé bí a bá le ti ipasẹ̀ òfin jèrè òdodo, a jẹ́ pé Kristi kú lásán.”

个人灵修·旧约/诗篇

에스겔 29

打开经文 →
第29章

Judgment on Pharaoh of Egypt Like a Great Monster

1Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹwàá, ọdún kẹwàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

2“Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Farao ọba Ejibiti kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Ejibiti.

3Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

4Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ

5Èmi yóò sọ ọ́ nù sí aginjù

6Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé, Èmi ni Olúwa.

7Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n.

8“ ‘Nítorí náà, èyí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi, Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ.

9Ilẹ̀ Ejibiti yóò di aginjù àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa.

10nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ̀ Ejibiti di píparun àti ahoro, pátápátá, láti Migdoli lọ dé Siene, dé ààlà ilẹ̀ Kuṣi.

11Kò sí ẹsẹ̀ ènìyàn tàbí tí ẹranko tí yóò gba ibẹ̀ kọjá; ẹni kankan kò ní gbé ibẹ̀ fún ogójì ọdún.

12Èmi yóò sọ ilẹ̀ Ejibiti di ọ̀kan ní àárín àwọn ìlú tí ó di ahoro, fún ogójì ọdún, Èmi yóò sì fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sáàárín gbogbo ilẹ̀.

13“ ‘Ṣùgbọ́n báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní òpin ogójì ọdún, èmi yóò ṣa àwọn ará Ejibiti jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi tí a fọ́n wọn ká sí.

14Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Ejibiti padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Paturosi, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀.

15Ibẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba tí ó rẹlẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọba, kì yóò sì gbé ara rẹ̀ ga mọ́ sórí àwọn orílẹ̀-èdè: nítorí èmi ni ó dín wọn kù, tiwọn kì yóò fi ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́.

16Ejibiti kí yóò sì jẹ orísun ìgbẹ́kẹ̀lé fún ilé Israẹli mọ́ ṣùgbọ́n, yóò jẹ́ ìrántí fún àìṣedéédéé wọn, nígbà tí yóò bá wò wọ́n fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.’ ”

The Land of Egypt Given to Nebuchadnezzar

17Ó sì ṣe ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní, ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

18“Ọmọ ènìyàn, Nebukadnessari ọba Babeli mú kí ogun rẹ sin ìrú ńlá fún Tire. Gbogbo orí pá, àti gbogbo èjìká bó, síbẹ̀, òun àti àwọn ogun rẹ̀, kò rí owó ọ̀yà gbà láti Tire fún wa, fún ìrú ti a ti sìn.

19Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, Èmi yóò fi Ejibiti fún Nebukadnessari ọba Babeli, òun yóò sì kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ. Òun yóò bo ilé, yóò sì ṣe ìkógun ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ tí a san fún ológun rẹ̀.

20Èmi ti fi Ejibiti fún un gẹ́gẹ́ bí èrè wàhálà rẹ̀ nítorí òun àti àwọn ológun rẹ ṣe é fún mi, ni Olúwa Olódùmarè wí.

21“Ní ọjọ́ náà, èmi yóò mú kí ìwo Israẹli ru jáde, èmi yóò sì fún ọ ní ẹnu ọ̀rọ̀ ní àárín wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”

个人灵修·新约

시편 78:1-37

打开经文 →
第78章

God's Deeds Handed Down to the Generations

1Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi;

2Èmi ó la ẹnu mi ní òwe,

3ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,

4Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́

5Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu

6nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n

7Nígbà náà ni wọ́n ò fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run

8Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn,

9Àwọn ọkùnrin Efraimu, tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun,

10Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́

11Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe,

12Ó ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Ejibiti, ní agbègbè Ṣoani.

13Ó pín òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá

14Ní ọ̀sán, ó fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn

15Ó sán àpáta ní aginjù

16Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta

17Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i

18Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò

19Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé

20Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde,

21Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi;

22nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́,

23Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run,

24Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ,

25Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli;

26Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá

27Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀,

28Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn,

29Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ

30Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún,

31ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn

32Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ síwájú;

33O fi òpin sí ayé wọn nínú asán

34Nígbàkígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n,

35Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn;

36Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́n

37ọkàn wọn kò sòtítọ́ sí i,