“ ‘Bí ẹnìkan bá mú ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ wá fún Olúwa ọrẹ rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára, kí ó da òróró sí i, kí o sì fi tùràrí sí i,
KO
Copywork
Yoruba OYCB 레위기 2장
성경필사는 빠르게 끝내는 입력 훈련이 아니라, 한 절씩 말씀의 문장과 흐름을 다시 붙드는 시간입니다. 입력 내용은 이 브라우저에 임시 저장되며, 로그인하면 계정에도 저장됩니다.
소제목 단위로 진행 · 레위기
kí ó sì gbé lọ fún àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà. Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ìyẹ̀fun àti òróró náà, pẹ̀lú gbogbo tùràrí kí ó sì sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lórí pẹpẹ, ọrẹ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
Ìyókù nínú ọrẹ ohun jíjẹ náà jẹ́ ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ ìpín tí ó mọ́ jùlọ nínú ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.
“ ‘Bí ẹ bá mú ọrẹ ohun jíjẹ, èyí tí a yan lórí ààrò iná, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára, àkàrà tí a ṣe láìní ìwúkàrà, tí a sì fi òróró pò àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a ṣe láìní ìwúkàrà èyí tí a fi òróró pò.
Bí ọrẹ ẹbọ rẹ bá jẹ́ inú àwo pẹẹrẹ ni o ti ṣe ohun jíjẹ rẹ, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára tí a fi òróró pò, kò sì gbọdọ̀ ní ìwúkàrà.
Rún un kí o sì da òróró sí i lórí, ọrẹ ohun jíjẹ ni.
Bí ọrẹ ẹbọ rẹ bá jẹ́ ẹbọ ohun jíjẹ, tí a yan nínú apẹ, ìyẹ̀fun dáradára ni kí o fi ṣè é pẹ̀lú òróró.
Mú ọrẹ ohun jíjẹ tí a fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe wá fún Olúwa gbé e fún àlùfáà, ẹni tí yóò gbe e lọ sí ibi pẹpẹ.
Àlùfáà yóò sì mú ẹbọ ìrántí nínú ọrẹ ohun jíjẹ yìí, yóò sì sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
Ìyókù nínú ọrẹ ohun jíjẹ yìí jẹ́ ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ èyí tí ó mọ́ jùlọ nínú ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.
“ ‘Gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ tí ẹ bá mú wá fún Olúwa kò gbọdọ̀ ní ìwúkàrà nínú, nítorí pé ẹ kò gbọdọ̀ sun ohun wíwú tàbí oyin nínú ọrẹ tí ẹ fi iná sun sí Olúwa.
Ẹ lè mú wọn wá fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àkọ́so ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ mú wọn wá sórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn.
Ẹ fi iyọ̀ dun gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ yín. Ẹ má ṣe aláìfi iyọ̀ májẹ̀mú Ọlọ́run yín sínú àwọn ọrẹ ohun jíjẹ yín, ẹ fi iyọ̀ sí gbogbo ọrẹ yín.
“ ‘Bí ẹ bá mú ọrẹ ohun jíjẹ ti àkọ́so oko yín wá fún Olúwa kí ẹ mú ọkà tuntun tí a fi iná yan.
Kí ẹ da òróró lé e lórí, kí ẹ sì fi tùràrí sí i, ó jẹ́ ọrẹ ohun jíjẹ.
Àlùfáà yóò sun ẹbọ ìrántí lára ọkà àti òróró náà, pẹ̀lú gbogbo tùràrí gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.