Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ní Sioni;
Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà,
Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni!
Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn
Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohun ìyanu ti òdodo,
ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ,
ẹni tí ó mú rírú omi òkun dákẹ́,
Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù,
Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin;
Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀
Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé,
Pápá tútù ní aginjù ń kan
Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà ní aṣọ;