Tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetísílẹ̀ kí o sì ní òye sí i.
JA
Copywork
Yoruba OYCB Proverbs 4장
写経は速く終える入力練習ではなく、一節ずつみ言葉の文と流れを改めて受け止める時間です。入力内容はこのブラウザに一時保存され、ログインするとアカウントにも保存されます。
小見出し単位で進める · Proverbs
Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro,
Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí,
Ó kọ́ mi ó sì wí pé,
Gba ọgbọ́n, gba òye,
Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́,
Ọgbọ́n ni ó ga jù; nítorí náà gba ọgbọ́n.
Gbé e ga, yóò sì gbé ọ ga
Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹ
Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ,
Mo tọ́ ọ ṣọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n
Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́
Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ;
Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú
Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀;
Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi,
Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búburú
Ipa ọ̀nà olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn
ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri;
Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ;
Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójú
nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọn
Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́,
Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ;
Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú,
Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ
Má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì;